Ayé yí
padà
Ayé yí
padà ayé dòdì àdá
Ìgbà yí
padà ó dè̩yìn ò̩be̩
Gbogbo ohun
lo̩ látorí kòdì
Bí wo̩n se
ń pé̩ láya ńjo̩un
Ni wo̩n ń
pé̩ láyé kánrinkése
Báwa se ń
káńjú lábè̩é̩ gbóná
Là ń
kánjú rèwàlè̩ àsà
Bó̩wó̩
wo̩n ò bá tétí
Iléèwé
ò le di lílo̩
Ni wó̩n fi
ń kó̩gbó̩n ilé
Kó tó
ko̩gbó̩n oko
Àwa ò
bèsù bè̩gbà
Bí wó̩n
bí wa sílè̩
A ó
bè̩rè̩ sùkúù
Àìdúró
gbè̩kó̩ ilé
Tá a fi ń
nanu mó̩ tìta
Báa bá
wá kàwé ò̩ún tán
Kì í
wúlò láìsé̩kò̩ó̩ ilé
A ti
kó̩kó̩ sè̩kó̩o̩lé nù
A sàpò
ìyà kó̩rí
A sapó
ìyá kó̩rùn
Às̩à
alás̩à la gbégúnwó̩
Tí gbogbo
wa ń mú soge
Obìnrin ò
lójú tì
Láti
bé̩wùú lè̩ ní pópó
Wo̩n a wo̩s̩o̩
sárasí
Gbogbo ayé
á máa róhun wo̩n ń mú soge
Lakó̩ fi
ń so̩ wó̩n dàpò è̩s̩é̩
Tó̩ko̩ ń
so̩ wó̩n di bàrà lílù
Ohun ojú
wo̩n ń rí
Wo̩n ó tó
láfè̩é̩só̩nà
Ni wó̩n fi
ń sàlè jè̩jè̩
Bí e̩ni ò
róbìnrin rí
Ni wó̩n fi
ń káya ilé wo̩n bí ojú wo̩n
O̩ko̩ è é
sèyí a ̀á yàn ló̩nà
E̩bí i
wo̩n ní báwo̩n wáko̩’re
Wo̩n á
túdìí ako̩ náà fínnífínní
Wo̩n á mo̩
irú e̩bí tí wo̩n ń se
Okinni tó
lókùn nídìí kìí nù
Tó bá
so̩nù
A ó to̩pa
okuǹ rè̩ lo̩ ni
O̩ko̩ táwa
kò lo̩nà
Tá à mo̩
irú e̩bí tó ti wá
Tá a kó
délé o̩ko̩ tán
Tó̩
jé̩wó̩ ohun té̩bí wó̩n ń se
Tó di Táísò̩n
táwa dàpò è̩sé̩
Tó di
mé̩sì táwa di bó̩ò̩lù
0 comments:
Post a Comment